Oriki Ogotun-Ekiti

The traditional praise chant celebrating the heritage, legacy, and noble lineage of Ogotun-Ekiti and its people.

Oriki Ogotun-Ekiti

The traditional praise chant that captures the essence, heritage, and noble lineage of our great town

Sacred Words of Our Heritage

Passed down through generations, these words celebrate our royal lineage and cultural identity

OMO OLOGOTUN OGBOLU, OMO AMURU EKUN SERE NIMUJA, OMO ELENI EWELE, EJA IDADE ORI AFI TI OWENA TO NDADE AKUN

OLOGOTUN OJUGBULENY, OSASANKALE RIBUJE, OKO OLORI ABAO JIJA. OKO OLORI ABA DIDAN, OMO OLURE KO GUN GOGORO JODI, URE KO PEREMOLE OMO OWA OMO EKUN, OMO AGBOGBOMOJA, OMO AMUNIJE MORARUN, OMO AWERIJI OLORI KEE YASO LAAFIN, OMO ELEJO KO MOKE ERURU SONA, OMO ELEJO KO MU GBOGBO ARA SIPOLO, OMO APURULEJU OMI KEE JOBITAN RIAN PONMI, ALLAYE OORUN ABA LOGOTUN EJI WELEWELE EJI A DE KEE MO BOORUN MOLE

OMO OLSE KO GUN GOGORO JODI, OMO OWA OMO EKUN, OMO APAGBO SOJU EBO MU SOORO KUN AGBO OJU EBO MUKU GBIGBI LOWA ITA OMO OLUPE YIYUN ATANNIJAGUN, OMO OLUPE REBE YUN-UN

OMO AFINJU EJA KEE LABU LAGURO OWENA, OSIKA NIYAN KOI OLOGOTUN JIORO, O PEJI NINU EJA OWENA, O DE MU KUGBA ONI JE, OMO ALALE ERE ONA IKATO, ALE ERE, KAN-AN TII KOGUNRAN KAN DE DIGBA USU TORE, OMO OPE UNU ODI KO DARAN, OPE UNU ODI KO HU BI ADODO, OPE UNU ODO KO DA BU AN MEDENI, OMO ELEJA KEE TO TE TE TE, EJA KO RUGIDI ROWENA, OMO ELEJA KO LU RERE ROKUN OBA KAN RUNNU ADE, AFOLOGOTUN

OMO ASORO RAJA MOGBO A A SORO KOYELE KAN-AN KAN MOYE

AKUKO NUKANKO KO LIBE LEE KO RI RI RI

OMO MO SANRIBOKO, MERAN AGBA ULODA LERU

AGBA ULODA KO PUKOKO AGUNTAN, KO PUKOKO ESI KAN-AN UN OBIRIN JE

OMO OLOJA UMURE UGBOORO
IGI AGBOGBO, OJA UMURE KAN-AN
MUSU U PESEJI AILOO KUUSE EBILULERE
OMO OBIFAKIN, ELEGBO OSE
OSE KAN-AN POYI KA KAN-AN SE MOMO RIAN KOKO

OMO OLOSE KO TU KEKE KO TIN KEKE BI ORI USU
OMO OLOSE KAN-AN BULA BULA DEGBEJE
OMO AKERE ALAIKA POJO ONIYAN LERU
OMO ALARUKO MERO TITI LOJA ARUKO BAN-AN YOKO IJO KAN
OLE NI LULE UFAKIN
OMO ABA OKE OJA GERE ETIPA
OTEMO LEHIN KESE DUGBA OJUJU

OMO JAKA LOJU ERIN
OJAKUN BI EKIRI
OMO DUBA AMARIGUN GBA YEGI

ETU GERELEL KAN-AN MII MEGBE ODASHA OKE UBA

MII MEE RELE YAA METUU MI DERI
OMO ALAAGBA SO BI UTI ORO
AGBAAGBA GBA LARIGBA O NA OKO ULE UDOGI
EURE PULARI LOKE UBA AN O TESE OI
AGUNTAN PULARI LOKE UBA
AN I AN TEJEMU
OMO AGAN KO YA SULE RIA KEE BI AGAN ORISA LEERE

OMO KAN KO JORUKO BAGAN LODI ONA OKE UBA
AJEJI JOKO LERI OTA LUGBONA KAN-AN MENI KOMI
OMO OLUMOGUN ARISORAN KEEWAJA
I SE NAN AN SORAN KAN AN
TO DENI OGUN OMO YEJARANU

NJEKA KITIPA KAN-AN MU
DE ALAIGBORAN E E LORI OGUN PETU
AGBARA LAJA MEJI O KEE
SOLOMU I KOLOMU MOKO KEE TU MOGUN PETU SE

OLOGOTUN OJORUBE AMURU EKU SERE LIMUJA

OMO EKUN OMO ONI OMO AMUNIMADA

OMO AMUGUN RUBO KERU BADIYE ONI

OMO AMIKIRIKI RUBO KERE A BAGBA ITOO

AMOMO RUBO KEYE RE KARUFIN ARUFI EBO ARUDA EBO

OMO OLURE KO GUN GOROGORO JODI URE KE JOLORI RAHUN UDENA ODO

KODA KOLORI RAUN UGBEE LURI A KANPA OTUN

OMO OMITERE AJEJI KO WESE, AJEJI KO WESE LIBE A DONI EBO

OMO EKUN TEERE KEE RUNBEBE UPEPE OMO EKUN KO FUN TORITORI, EKUN KO FUN TURUTURU

OLOGOTUN SAANU EYI OGOTUN O MINUJU OKE GBERE, I KO SO KEE SO

IFA RE TEYE OKO NU OMO ALAYAN MI KARA MEFA ETA TOWA ETE TOMO OMO ALIBARA ALUJAGBORO OORO

OMO ALIBARA ARIRO IDE WANRAN WANRAN OMO APAGBO SOJU EBO MU SOORO KUN OMO ELENI ATEEKA

OMO ELENI EWELE , OKO DUDU OKO PUPA, O SOKO EKITI SOKO AKOKO ENI AKOKO BIMOO DE LOSE OKE

PLACEHOLDER

OLOGOTUN AGUNBIADE, OJAAGUN JABA, O JAGUN NILE OJAGUN LEGBE, EJA DADE ORI TOWENA NUKAN LEE DADE AKUN

OMO EYEWENA UJIODO OKU SOMO KONRIN OBILARA O BI LAPA O MOLOGOTUN SAKOBI

ONII GBO KOGOKOGO AOGO LODO OMO UJI ODO OTETE, EJIN-IN-RIN FA BOLE ALARIGBORAN, EYE ORUNMOYE UJU, EYE EJEMU LIJIGBA OORE YEEYE O

JAN-AN MEUN MEJI SUBOKO LUFAKIN, ONI MEMU MEJISU ROKO ODARA GBAKAN ODARA GBAKAN TAN O MUREBORUN

ARUKP BAN-AN YOKO IJOKAN AN DITE E RE, ARUKO BAN-AN YOKO IJOKAN AN I OLE NI

OMO OLOJA OWO ANANDORU SURUGUDU OMO OLOPOPO ONA IJISUN, OBANIFON ODARA LOSI OBANIFO YETE, URO UNA APAPAMAJA, AJA MA O KO SERI OMO KORO ULE OLOGBO, KO MAGBA UFAKIN RERO

OKEMI ALE OORO, OMO ATOKOBO MOHUN SIBIKAN NI

ODOFIN OKEMI, OMO AMON ASOJU OMI KOSE MO SERIKI

OMO OLUMOSE OMO ATIKUN AYA FO'UN

OMO ALU GU DU GU DU NO WA SOGUN

OMO ALAKO SORUN GBA LUGO

AKO KO SUDI SARA SU LENI LORI

KOLUMOSE BA AKO RE WIJO

AKO YEYE KEKUN OMO AMONA

OMO OLOGOTUN OMO OLORE

ELEYIN FIFUN-UN FO LAJO

ODOFIN LA MOHUN UN-UN SI LENU, OMO OLUMOSE, OMO MEEGUN KEE KE KARA

EMINISE OKEMI O RETU RI FILA, EMINISE LO LURO

AGUNTAN DAGIRI, KAN AN MII SOMODE EMINISE

OMO EJO RIR ATANA, EO KO PURU LEJU OMI KE JAYABA PONMI, OUN LO PURO LEJU OMI KE JERO EKITI WESE

OMO OLOPE RANYIN RANYIN IKATO, OPE RAN IIN RAN IIN KAN-AN MU LIKATO EKUTE JERUN ONI SINMI

OMO OLI SESEKI ORI ADE KAN-AN RORIRE E WO

AIROBOLOJA A SAGBE E JEMI YA KOKO LIKATO OKO OBA, OMO ELEJO KERIN TOROWA LOSAN GANGAN

OMO ERUKU GEDE KEE JERU OBA RAUN TYOO PE EKODA KERU OBA RAUN I KERU GEDE DIYO

OBILODA OMO ALAGIDANYIN AGIDANYIN ARUDABO OSORI EPE TIRE O SERUN AGADA JUURU

OMO ADIGBOORO KUNRAN ESI OMO OLULE OMOMI KO KANRUN ODI, OBAYYANKUN UGBA EGBE MOO SENI ORIRE

UGBIN UGBA EGBE FAARE OGBERE E GBODO KELULE RE, OMO AGBARA META SANGIDI TOKEE BO

OKAN YA SULE OSOLO, OKAN YA SULE AREMO, OKAN KO GBOJUU LIBE OSANGIDI ROWENA

OMO OTA GBASAA OMO OTA GOGORO, OTA SEENU OTA GBEKAN RE LERI

OMO OTA KAN KO GBIJESA SISUN, BAA LOR KOLOMO MOKO KEE TU MOGUN OMO WERE SE

OMO OLUGBOGBO PESI MEJI KAGBA UWARA GBEKAN I KOMODE GBEKAN, KAN A PIN A JE

I UTAN RE TELEJIO ABA OJUSHE, OMO OLOSUN UJU AMUROGBO BI AKUN AKOKO SEE LIBE OSE RURO OYUN, AGBEYIN SEE LIBE OS SEGI

OMO OLULE UREGBETE ONA IKADU, ISU KAN-AN RI GBOGBO, KAN AN RI GBOGBO LIGADAN UBETE NAN MU SE LIJO OSUN ADODO

OMO AMURUKERE DAMO LORI LORI UDE

OMO OGBONI DAJO OLOMINRIN

E SONI DAJO OGBONI

The Living Heritage

These sacred words echo through time, connecting us to our ancestors and affirming our identity as the children of Ologotun. They speak of our noble lineage, our courage like the leopard, and our unbreakable bond to this blessed land.

Experience Our Rich Heritage

From ancient traditions to modern achievements, discover why our town continues to be a beacon of Yoruba heritage and community excellence.

"A town where ancient traditions meet modern aspirations"